Amos 3

Ẹ̀rí jíjẹ́ nípa àwọn ọmọ Israẹli

1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:

2“Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn
nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;
nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà
fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

3Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀
láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ?
4Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó,
bí kò bá ní ohun ọdẹ?
Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀
bí kò bá rí ohun kan mú?
5Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀
nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?
Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀
nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
6Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú,
àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù?
Tí ewu bá wa lórí ìlú
kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?

7 aNítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan
láìfi èrò rẹ̀ hàn
fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

8Kìnnìún ti bú ramúramù
ta ni kì yóò bẹ̀rù?
Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀
ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?

9Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu
àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria;
Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀
àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”

10“Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,
“àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
11Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;
yóò wó ibi gíga yín palẹ̀
a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì
kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan
bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,
tí ń gbé Samaria kúrò
ní igun ibùsùn wọn
ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”
13“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.

14“Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run;
ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò
yóò sì wó lulẹ̀.
15Èmi yóò wó ilé òtútù
lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;
ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé
a ó sì pa ilé ńlá náà run,”
ni Olúwa wí.
Copyright information for YorBMYO